-
Ẹ́kísódù 29:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
29 “Ohun tí o máa ṣe láti yà wọ́n sí mímọ́ kí wọ́n lè di àlùfáà mi nìyí: Mú ọmọ akọ màlúù kan, àgbò méjì tí kò ní àbùkù,+ 2 búrẹ́dì aláìwú, búrẹ́dì aláìwú tí wọ́n pò mọ́ òróró, tó rí bí òrùka àti búrẹ́dì aláìwú pẹlẹbẹ tí wọ́n fi òróró pa.+ Ìyẹ̀fun àlìkámà* tó kúnná ni kí o fi ṣe wọ́n. 3 kí o wá kó wọn sínú apẹ̀rẹ̀, kí o sì fi apẹ̀rẹ̀ náà gbé e wá,+ pẹ̀lú akọ màlúù àti àgbò méjì náà.
-
-
Léfítíkù 6:14, 15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 “‘Òfin ọrẹ ọkà+ nìyí: Kí ẹ̀yin ọmọ Áárónì mú un wá síwájú Jèhófà, ní iwájú pẹpẹ. 15 Kí ọ̀kan lára wọn bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun tó kúnná nínú ọrẹ ọkà àti díẹ̀ lára òróró rẹ̀ àti gbogbo oje igi tùràrí tó wà lórí ọrẹ ọkà, kó sì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ láti mú òórùn dídùn* jáde sí Jèhófà, kó fi ṣe ọrẹ ìṣàpẹẹrẹ.*+
-