25 Kí àlùfáà wá gba ọrẹ ọkà owú+ náà lọ́wọ́ obìnrin náà, kó fi ọrẹ ọkà náà síwá-sẹ́yìn níwájú Jèhófà, kó wá gbé e sún mọ́ pẹpẹ. 26 Kí àlùfáà bu ẹ̀kúnwọ́ ọrẹ ọkà náà láti fi ṣe ọrẹ ìṣàpẹẹrẹ, kó sì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ,+ lẹ́yìn náà, kó mú kí obìnrin náà mu omi náà.