-
Ẹ́kísódù 29:24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Kí o kó gbogbo wọn sí ọwọ́ Áárónì àti sí ọwọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, kí o sì fì wọ́n síwá-sẹ́yìn bí ọrẹ fífì níwájú Jèhófà.
-
-
Léfítíkù 8:25-27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Ó wá mú ọ̀rá rẹ̀, ìrù ọlọ́ràá, gbogbo ọ̀rá tó wà lára ìfun, àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀, kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá wọn, pẹ̀lú ẹsẹ̀ ọ̀tún.+ 26 Ó mú búrẹ́dì aláìwú kan tó rí bí òrùka,+ búrẹ́dì kan tí wọ́n fi òróró sí tó rí bí òrùka+ àti búrẹ́dì pẹlẹbẹ kan látinú apẹ̀rẹ̀ búrẹ́dì aláìwú tó wà níwájú Jèhófà. Ó sì kó wọn sórí àwọn ọ̀rá náà àti ẹsẹ̀ ọ̀tún. 27 Lẹ́yìn náà, ó kó gbogbo rẹ̀ sórí àtẹ́lẹwọ́ Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fì ọrẹ náà síwá-sẹ́yìn bí ọrẹ fífì níwájú Jèhófà.
-
-
Léfítíkù 9:21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 Àmọ́ Áárónì fi àwọn igẹ̀ àti ẹsẹ̀ ọ̀tún síwá-sẹ́yìn bí ọrẹ fífì níwájú Jèhófà, bí Mósè ṣe pa á láṣẹ.+
-