12 Mósè wá sọ fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù, Élíásárì àti Ítámárì pé: “Ẹ kó ọrẹ ọkà tó ṣẹ́ kù látinú àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, kí ẹ fi ṣe búrẹ́dì aláìwú, kí ẹ sì jẹ ẹ́ nítòsí pẹpẹ,+ torí pé ohun mímọ́ jù lọ ni.+
9 Èyí ló máa jẹ́ tìrẹ nínú ọrẹ mímọ́ jù lọ tí wọ́n fi iná sun: gbogbo ọrẹ tí wọ́n bá mú wá, títí kan àwọn ọrẹ ọkà+ wọn àtàwọn ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ wọn pẹ̀lú àwọn ẹbọ ẹ̀bi+ wọn tí wọ́n mú wá fún mi. Ohun mímọ́ jù lọ ló jẹ́ fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ.