-
Léfítíkù 5:11, 12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 “‘Tí agbára rẹ̀ ò bá wá ká ẹyẹ oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì, kó mú ìyẹ̀fun tó kúnná tó jẹ́ ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà*+ wá láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ torí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá. Kó má da òróró sí i, kó má sì fi oje igi tùràrí sí i, torí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni. 12 Kó gbé e wá fún àlùfáà, kí àlùfáà sì bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun náà, kó fi ṣe ọrẹ ìṣàpẹẹrẹ,* kó sì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ lórí àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà. Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni.
-