9 Kó mú ọ̀rá látinú ẹbọ ìrẹ́pọ̀, kó fi ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà.+ Kó gé ìrù rẹ̀ tó lọ́ràá nítòsí eegun ẹ̀yìn kúrò lódindi, ọ̀rá tó bo ìfun, gbogbo ọ̀rá tó yí ìfun ká, 10 pẹ̀lú kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá tó wà lára wọn nítòsí abẹ́nú. Kó tún yọ àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀ pẹ̀lú àwọn kíndìnrín+ náà.