-
Léfítíkù 9:18-20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Lẹ́yìn ìyẹn, ó pa akọ màlúù àti àgbò ẹbọ ìrẹ́pọ̀ tó jẹ́ ti àwọn èèyàn náà. Àwọn ọmọ Áárónì wá gbé ẹ̀jẹ̀ náà fún un, ó sì wọ́n ọn yí ká gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ.+ 19 Ní ti àwọn ọ̀rá akọ màlúù náà,+ ìrù àgbò náà tó lọ́ràá, ọ̀rá tó bo àwọn ohun tó wà nínú ẹran náà, àwọn kíndìnrín àti àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀,+ 20 wọ́n kó gbogbo àwọn ọ̀rá náà sórí àwọn igẹ̀, lẹ́yìn náà, ó mú kí àwọn ọ̀rá náà rú èéfín lórí pẹpẹ.+
-