-
Léfítíkù 15:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Tí ẹni tí nǹkan ń dà jáde lára rẹ̀ bá tutọ́ sára ẹni tó mọ́, kí ẹni náà fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, kó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.
-
-
Léfítíkù 22:4-6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Ìkankan nínú àwọn ọmọ Áárónì tó bá jẹ́ adẹ́tẹ̀+ tàbí tí nǹkan ń dà lára rẹ̀+ ò gbọ́dọ̀ jẹ nínú àwọn ohun mímọ́ títí ẹni náà yóò fi di mímọ́,+ bẹ́ẹ̀ náà ni ẹnikẹ́ni tó bá fara kan ẹni tí òkú èèyàn* sọ di aláìmọ́+ tàbí ọkùnrin tó ń da àtọ̀+ 5 tàbí ẹni tó bá fara kan ẹ̀dá tó ń gbá yìn-ìn+ tó jẹ́ aláìmọ́ tàbí tó fara kan ẹnì kan tí ohunkóhun mú kó di aláìmọ́, tó sì lè sọ ọ́ di aláìmọ́.+ 6 Ẹni* tó bá fara kan ìkankan nínú ìwọ̀nyí yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́, kó má sì jẹ ìkankan nínú àwọn ohun mímọ́, àmọ́ kó fi omi wẹ̀.+
-