-
Léfítíkù 11:24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Ẹ lè fi nǹkan wọ̀nyí sọ ara yín di aláìmọ́. Gbogbo ẹni tó bá fara kan òkú wọn yóò di aláìmọ́ títí di alẹ́.+
-
-
Léfítíkù 22:4, 5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Ìkankan nínú àwọn ọmọ Áárónì tó bá jẹ́ adẹ́tẹ̀+ tàbí tí nǹkan ń dà lára rẹ̀+ ò gbọ́dọ̀ jẹ nínú àwọn ohun mímọ́ títí ẹni náà yóò fi di mímọ́,+ bẹ́ẹ̀ náà ni ẹnikẹ́ni tó bá fara kan ẹni tí òkú èèyàn* sọ di aláìmọ́+ tàbí ọkùnrin tó ń da àtọ̀+ 5 tàbí ẹni tó bá fara kan ẹ̀dá tó ń gbá yìn-ìn+ tó jẹ́ aláìmọ́ tàbí tó fara kan ẹnì kan tí ohunkóhun mú kó di aláìmọ́, tó sì lè sọ ọ́ di aláìmọ́.+
-