3 Ì báà jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, ṣe ni kí ẹ ní kí wọ́n jáde. Kí ẹ ní kí wọ́n lọ sí ẹ̀yìn ibùdó, kí wọ́n má bàa kó èérí bá+ àgọ́ àwọn tí mò ń gbé+ láàárín wọn.”*
20 “‘Àmọ́ tí ẹnì kan bá jẹ́ aláìmọ́, tí kò sì wẹ ara rẹ̀ mọ́, ṣe ni kí ẹ pa ẹni* náà kúrò láàárín ìjọ,+ torí ó ti sọ ibi mímọ́ Jèhófà di aláìmọ́. Aláìmọ́ ni torí wọn ò wọ́n omi ìwẹ̀mọ́ sí i lára.