25 “‘Tí ẹ̀jẹ̀ bá ń dà lára obìnrin kan fún ọ̀pọ̀ ọjọ́,+ tó sì jẹ́ pé àkókò tó máa ń rí nǹkan oṣù rẹ̀ kò tíì tó+ tàbí tí iye ọjọ́ tí ẹ̀jẹ̀ fi dà lára rẹ̀ bá pọ̀ ju iye tó máa ń jẹ́ tó bá ń ṣe nǹkan oṣù, aláìmọ́ ni yóò jẹ́ ní gbogbo ọjọ́ tí ẹ̀jẹ̀ bá fi ń dà lára rẹ̀, bí ìgbà tó ń ṣe nǹkan oṣù.