-
Léfítíkù 14:7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Kó wá wọ́n ọn lẹ́ẹ̀méje sára ẹni tó fẹ́ wẹ ara rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀tẹ̀, kó sì kéde pé ẹni náà ti di mímọ́, kó sì tú ààyè ẹyẹ náà sílẹ̀ lórí pápá gbalasa.+
-
-
Léfítíkù 14:53Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
53 Kó wá tú ààyè ẹyẹ náà sílẹ̀ ní ẹ̀yìn ìlú náà, lórí pápá gbalasa, kó sì ṣe ètùtù fún ilé náà, ilé náà yóò sì di mímọ́.
-
-
Léfítíkù 16:21, 22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 Kí Áárónì gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé orí ààyè ewúrẹ́ náà, kó jẹ́wọ́ gbogbo àṣìṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti gbogbo ìṣìnà wọn àti gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn sórí rẹ̀, kí ó kó o lé orí ewúrẹ́+ náà, kó wá yan ẹnì kan* tó máa rán ewúrẹ́ náà lọ sínú aginjù. 22 Kí ewúrẹ́ náà fi orí rẹ̀ ru gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn+ lọ sí aṣálẹ̀,+ kó sì rán ewúrẹ́ náà lọ sínú aginjù.+
-
-
Àìsáyà 53:4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
Àmọ́ a kà á sí ẹni tí ìyọnu bá, ẹni tí Ọlọ́run kọ lù, tó sì ń jìyà.
-