-
Ẹ́kísódù 30:34-36Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
34 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Mú àwọn lọ́fínńdà yìí ní ìwọ̀n kan náà:+ àwọn ẹ̀kán sítákítè, ọ́níkà, gábánọ́mù onílọ́fínńdà àti ògidì oje igi tùràrí. 35 Kí o fi ṣe tùràrí;+ kí o ro àwọn èròjà náà pọ̀ dáadáa,* fi iyọ̀ sí i,+ kó jẹ́ ògidì, kó sì jẹ́ mímọ́. 36 Kí o gún lára rẹ̀, kó sì kúnná, kí o wá bù lára rẹ̀ síwájú Ẹ̀rí nínú àgọ́ ìpàdé, níbi tí màá ti pàdé rẹ. Kó jẹ́ mímọ́ jù lọ fún yín.
-
-
Ìfihàn 8:3-5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Áńgẹ́lì míì dé, ó dúró níbi pẹpẹ,+ ó gbé àwo tùràrí tí wọ́n fi wúrà ṣe* dání, a sì fún un ní tùràrí tó pọ̀ gan-an+ pé kó sun ún lórí pẹpẹ tí wọ́n fi wúrà ṣe+ tó wà níwájú ìtẹ́ náà bí gbogbo àwọn ẹni mímọ́ ṣe ń gbàdúrà. 4 Èéfín tùràrí látọwọ́ áńgẹ́lì náà àti àdúrà+ àwọn ẹni mímọ́ gòkè lọ síwájú Ọlọ́run. 5 Àmọ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, áńgẹ́lì náà mú àwo tùràrí náà, ó kó díẹ̀ lára iná pẹpẹ sínú rẹ̀, ó sì jù ú sí ayé. Ààrá sán, a gbọ́ ohùn, mànàmáná kọ yẹ̀rì,+ ìmìtìtì ilẹ̀ sì wáyé.
-