17 “Tí ẹnì* kan bá ṣe èyíkéyìí nínú àwọn ohun tí Jèhófà pa láṣẹ pé kí ẹ má ṣe, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣẹ̀, bí kò bá tiẹ̀ mọ̀, yóò jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ torí ó ṣì jẹ̀bi.+
27 “‘Tí ẹnikẹ́ni* bá ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀, kó mú abo ewúrẹ́ ọlọ́dún kan wá láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.+28 Kí àlùfáà sì ṣe ètùtù fún ẹni* tó ṣe àṣìṣe náà, tó ṣẹ̀ láìmọ̀ọ́mọ̀ níwájú Jèhófà, kó lè ṣe ètùtù fún un, ó sì máa rí ìdáríjì.+