-
Léfítíkù 8:15, 16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Mósè pa á, ó fi ìka rẹ̀ mú ẹ̀jẹ̀ ẹran náà,+ ó fi sára àwọn ìwo tó wà ní gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ, ó sì wẹ ẹ̀ṣẹ̀ kúrò lára pẹpẹ náà, àmọ́ ó da ẹ̀jẹ̀ tó kù sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ, kó lè yà á sí mímọ́ láti ṣe ètùtù lórí rẹ̀. 16 Lẹ́yìn náà, ó mú gbogbo ọ̀rá tó wà lára ìfun, àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀, kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá wọn, Mósè sì mú kí wọ́n rú èéfín lórí pẹpẹ.+
-