15 Tí ẹnikẹ́ni* bá jẹ òkú ẹran tàbí èyí tí ẹran inú igbó fà ya,+ ì báà jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ tàbí àjèjì ló jẹ ẹ́, kó fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, kó sì di aláìmọ́ títí di alẹ́;+ lẹ́yìn náà, á di mímọ́.
21 “Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ òkú ẹran èyíkéyìí.+ Ẹ lè fún àjèjì tó wà nínú àwọn ìlú* yín, kó sì jẹ ẹ́ tàbí kí ẹ tà á fún àjèjì. Torí pé èèyàn mímọ́ lẹ jẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run yín.