-
Léfítíkù 3:3-5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Kó fi lára ẹbọ ìrẹ́pọ̀ náà ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà:+ ọ̀rá+ tó bo ìfun, gbogbo ọ̀rá tó yí ìfun ká 4 àti kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tó wà lára wọn nítòsí abẹ́nú rẹ̀. Kó tún yọ àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀, pẹ̀lú àwọn kíndìnrín+ ẹran náà. 5 Kí àwọn ọmọ Áárónì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ, lórí ẹbọ sísun tó wà lórí igi lórí iná;+ ọrẹ àfinásun tó ní òórùn dídùn* ló jẹ́ sí Jèhófà.+
-