ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 61:1, 2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 61 Ẹ̀mí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wà lára mi,+

      Torí Jèhófà ti yàn mí kí n lè kéde ìhìn rere fún àwọn oníwà pẹ̀lẹ́.+

      Ó rán mi láti di ọgbẹ́ àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn,

      Láti kéde òmìnira fún àwọn ẹrú,

      Pé ojú àwọn ẹlẹ́wọ̀n sì máa là rekete,+

       2 Láti kéde ọdún ìtẹ́wọ́gbà* Jèhófà

      Àti ọjọ́ ẹ̀san Ọlọ́run wa,+

      Láti tu gbogbo àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú,+

  • Lúùkù 4:18, 19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 “Ẹ̀mí Jèhófà* wà lára mi, torí ó ti yàn mí kí n lè kéde ìhìn rere fún àwọn aláìní. Ó rán mi láti kéde òmìnira fún àwọn ẹrú, pé àwọn afọ́jú máa pa dà ríran, láti mú kí àwọn tí wọ́n tẹ̀ rẹ́ máa lọ lómìnira,+ 19 láti wàásù ọdún ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà.”*+

  • Róòmù 8:20, 21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 Nítorí a tẹ ìṣẹ̀dá lórí ba fún asán,+ kì í ṣe nípa ìfẹ́ òun fúnra rẹ̀, àmọ́ nípasẹ̀ ẹni tó tẹ̀ ẹ́ lórí ba, nítorí ìrètí, 21 kí a lè dá ìṣẹ̀dá fúnra rẹ̀ sílẹ̀+ lọ́wọ́ ẹrú ìdíbàjẹ́, kí ó sì lè ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́