-
Jẹ́nẹ́sísì 26:12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Ísákì bẹ̀rẹ̀ sí í dá oko ní ilẹ̀ náà. Lọ́dún yẹn, ó kórè ìlọ́po ọgọ́rùn-ún (100) ohun tó gbìn, torí Jèhófà ń bù kún un.+
-
-
Diutarónómì 28:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Jèhófà máa pàṣẹ ìbùkún sórí àwọn ilé ìkẹ́rùsí+ rẹ àti gbogbo ohun tí o bá dáwọ́ lé, ó sì dájú pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa bù kún ọ ní ilẹ̀ tó fẹ́ fún ọ.
-