-
Rúùtù 4:4-6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Torí náà, mo rò pé ó yẹ kí n sọ fún ọ nípa rẹ̀ pé, ‘Rà á níṣojú àwọn ará ìlú àti àwọn àgbààgbà àwọn èèyàn mi.+ Tí o bá máa tún un rà, tún un rà. Ṣùgbọ́n tí o kò bá ní tún un rà, jọ̀ọ́ sọ fún mi, kí n lè mọ̀, torí ìwọ lo lẹ́tọ̀ọ́ láti tún un rà, èmi ló sì tẹ̀ lé ọ.’” Ó dáhùn pé: “Màá tún un rà.”+ 5 Torí náà, Bóásì sọ pé: “Ní ọjọ́ tí o bá ra ilẹ̀ náà lọ́wọ́ Náómì, o tún gbọ́dọ̀ rà á lọ́wọ́ Rúùtù ará Móábù, aya ọkùnrin tó ti kú náà, kí o lè dá orúkọ ọkùnrin tó ti kú náà pa dà sórí ogún rẹ̀.”+ 6 Olùtúnrà náà fèsì pé: “Mi ò lè tún un rà, torí kí n má bàa run ogún tèmi. Mo yọ̀ǹda fún ọ láti tún un rà, torí mi ò ní lè tún un rà.”
-