16 Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Wò ó! O ò ní pẹ́ kú,* àwọn èèyàn yìí á sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ọlọ́run àjèjì tó yí wọn ká ní ilẹ̀ tí wọ́n ń lọ ṣe àgbèrè ẹ̀sìn.+ Wọ́n á pa mí tì,+ wọ́n á sì da májẹ̀mú mi tí mo bá wọn dá.+
9 Kò ní dà bíi májẹ̀mú tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá ní ọjọ́ tí mo dì wọ́n lọ́wọ́ mú láti mú wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ torí pé wọn ò pa májẹ̀mú mi mọ́, ìdí nìyẹn tí mi ò fi bójú tó wọn mọ́,’ ni Jèhófà* wí.