-
2 Àwọn Ọba 23:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Lẹ́yìn náà, ó kó gbogbo àwọn àlùfáà jáde kúrò ní àwọn ìlú Júdà, ó sì sọ àwọn ibi gíga tí àwọn àlùfáà ti ń mú ẹbọ rú èéfín di ibi tí kò ṣeé lò fún ìjọsìn, láti Gébà+ títí dé Bíá-ṣébà.+ Ó tún wó àwọn ibi gíga ẹnubodè tó wà ní ibi àtiwọ ẹnubodè Jóṣúà olórí ìlú náà, èyí tó wà lápá òsì tí èèyàn bá wọ ẹnubodè ìlú náà.
-
-
2 Àwọn Ọba 23:20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Torí náà, ó fi gbogbo àlùfáà àwọn ibi gíga tó wà níbẹ̀ rúbọ lórí àwọn pẹpẹ náà, ó sì sun egungun àwọn èèyàn lórí wọn.+ Lẹ́yìn náà, ó pa dà sí Jerúsálẹ́mù.
-
-
Ìsíkíẹ́lì 6:5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Èmi yóò ju òkú àwọn èèyàn Ísírẹ́lì síwájú àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn, èmi yóò sì fọ́n egungun yín ká sí àyíká àwọn pẹpẹ yín.+
-