17 Akọ màlúù tó jẹ́ àkọ́bí tàbí akọ ọ̀dọ́ àgùntàn tó jẹ́ àkọ́bí tàbí àkọ́bí ewúrẹ́ nìkan ni kí o má rà pa dà.+ Wọ́n jẹ́ ohun mímọ́. Kí o wọ́n ẹ̀jẹ̀ wọn sórí pẹpẹ,+ kí o sì mú kí ọ̀rá wọn rú èéfín bí ọrẹ àfinásun tó máa mú òórùn dídùn jáde sí Jèhófà.+