ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 14:20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 Ìyìn yẹ Ọlọ́run Gíga Jù Lọ,

      Ẹni tó mú kí ọwọ́ rẹ tẹ àwọn tó ń ni ọ́ lára!”

      Ábúrámù sì fún un ní ìdá mẹ́wàá gbogbo nǹkan.+

  • Jẹ́nẹ́sísì 28:22
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Òkúta tí mo gbé kalẹ̀ bí òpó yìí yóò di ilé Ọlọ́run,+ ó sì dájú pé màá fún ọ ní ìdá mẹ́wàá gbogbo ohun tí o fún mi.”

  • Nọ́ńbà 18:21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 “Wò ó, mo ti fún àwọn ọmọ Léfì ní gbogbo ìdá mẹ́wàá+ ní Ísírẹ́lì, kó jẹ́ ogún wọn torí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe, iṣẹ́ àgọ́ ìpàdé.

  • Nọ́ńbà 18:26
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 26 “Sọ fún àwọn ọmọ Léfì pé, ‘Ẹ ó máa gba ìdá mẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, èyí tí mo fún yín láti ọwọ́ wọn kó lè jẹ́ ogún+ yín, kí ẹ sì fi ìdá mẹ́wàá lára ìdá mẹ́wàá náà ṣe ọrẹ fún Jèhófà.+

  • Diutarónómì 14:22
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 “O gbọ́dọ̀ rí i pé ò ń san ìdá mẹ́wàá gbogbo ohun tí irúgbìn rẹ bá ń mú jáde lọ́dọọdún.+

  • 2 Kíróníkà 31:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 Gbàrà tí ọba pa àṣẹ náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkọ́so ọkà, wáìnì tuntun, òróró+ àti oyin pẹ̀lú gbogbo irè oko wá;+ wọ́n mú ìdá mẹ́wàá ohun gbogbo wá ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ.+

  • Nehemáyà 13:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Gbogbo Júdà sì kó ìdá mẹ́wàá+ ọkà àti ti wáìnì tuntun àti ti òróró wá sí àwọn yàrá tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí.+

  • Málákì 3:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Ẹ mú gbogbo ìdá mẹ́wàá wá sínú ilé ìkẹ́rùsí,+ kí oúnjẹ lè wà nínú ilé mi.+ Ẹ jọ̀ọ́, ẹ fi èyí dán mi wò,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí, “kí ẹ lè rí i bóyá mi ò ní ṣí ibú omi ọ̀run,+ kí n sì tú* ìbùkún sórí yín títí ẹ kò fi ní ṣaláìní ohunkóhun.”+

  • Lúùkù 11:42
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 42 Àmọ́ ẹ gbé ẹ̀yin Farisí, torí pé ẹ̀ ń san ìdá mẹ́wàá ewéko míńtì, ewéko rúè àti gbogbo ewébẹ̀* míì,+ àmọ́ ẹ ò ka ìdájọ́ òdodo àti ìfẹ́ Ọlọ́run sí! Àwọn nǹkan yìí ló pọn dandan kí ẹ ṣe, àmọ́ kò yẹ kí ẹ ṣàìka àwọn nǹkan yòókù yẹn sí.+

  • Hébérù 7:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 Lóòótọ́, bí Òfin ṣe sọ, a pàṣẹ fún àwọn ọmọ Léfì+ tí wọ́n gba iṣẹ́ àlùfáà wọn pé kí wọ́n máa gba ìdá mẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn èèyàn,+ ìyẹn lọ́wọ́ àwọn arákùnrin wọn, bí àwọn yìí tiẹ̀ jẹ́ àtọmọdọ́mọ* Ábúráhámù.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́