54 Kí ẹ fi kèké+ pín ilẹ̀ náà bí ohun ìní láàárín àwọn ìdílé yín. Kí ẹ fi kún ogún tí ẹ máa pín fún àwùjọ tó bá pọ̀, kí ẹ sì dín ogún+ tí ẹ máa pín fún àwùjọ tó bá kéré kù. Ibi tí kèké kálukú bá bọ́ sí ni ohun ìní rẹ̀ máa wà. Ẹ̀yà àwọn bàbá+ yín la máa fi pín ogún fún yín.