-
Ìṣe 6:5, 6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Ohun tí wọ́n sọ dùn mọ́ gbogbo àwọn èèyàn náà nínú, wọ́n sì yan Sítéfánù, ọkùnrin tó kún fún ìgbàgbọ́ àti ẹ̀mí mímọ́ pẹ̀lú Fílípì,+ Pírókórọ́sì, Níkánọ̀, Tímónì, Páménásì àti Níkóláósì tó jẹ́ aláwọ̀ṣe* ará Áńtíókù. 6 Wọ́n mú wọn wá sọ́dọ̀ àwọn àpọ́sítélì, lẹ́yìn tí àwọn àpọ́sítélì gbàdúrà, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn.+
-