-
Ẹ́kísódù 29:38Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
38 “Ohun tí ìwọ yóò fi rúbọ lórí pẹpẹ náà nìyí: ọmọ àgbò méjì tó jẹ́ ọlọ́dún kan lójoojúmọ́ títí lọ.+
-
-
Ẹ́kísódù 29:42Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
42 Kí ẹ máa rú ẹbọ sísun yìí nígbà gbogbo jálẹ̀ àwọn ìran yín ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé níwájú Jèhófà, níbi tí màá ti pàdé yín láti bá yín sọ̀rọ̀.+
-
-
2 Kíróníkà 2:4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Ní báyìí, mo fẹ́ kọ́ ilé fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run mi, láti yà á sí mímọ́ fún un, láti máa sun tùràrí onílọ́fínńdà+ níwájú rẹ̀ àti láti máa kó búrẹ́dì onípele* síbẹ̀ ní gbogbo ìgbà+ àti àwọn ẹbọ sísun ní àárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́,+ ní àwọn Sábáàtì,+ ní àwọn òṣùpá tuntun+ àti ní àwọn àsìkò àjọyọ̀+ Jèhófà Ọlọ́run wa. Ohun tí Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ máa ṣe nìyẹn títí láé.
-