-
Jóṣúà 22:7, 8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Mósè ti fún ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè ní ogún ní Báṣánì,+ Jóṣúà sì ti fún ààbọ̀ ẹ̀yà náà tó kù àti àwọn arákùnrin wọn ní ilẹ̀ ní ìwọ̀ oòrùn Jọ́dánì.+ Bákan náà, nígbà tí Jóṣúà ní kí wọ́n máa lọ sí àgọ́ wọn, ó súre fún wọn, 8 ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìní pa dà lọ sí àgọ́ yín, pẹ̀lú ẹran ọ̀sìn tó pọ̀, fàdákà àti wúrà, bàbà àti irin àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ aṣọ.+ Ẹ kó ìpín yín nínú ẹrù àwọn ọ̀tá yín,+ ẹ̀yin àtàwọn arákùnrin yín.”
-