ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 10:19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 Ààlà àwọn ọmọ Kénáánì bẹ̀rẹ̀ láti Sídónì títí lọ dé Gérárì,+ nítòsí Gásà,+ títí lọ dé Sódómù, Gòmórà,+ Ádímà àti Sébóíímù,+ nítòsí Láṣà.

  • Diutarónómì 4:38
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 38 Ó lé àwọn orílẹ̀-èdè tó tóbi, tí wọ́n sì lágbára jù ọ́ lọ kúrò níwájú rẹ, kó lè mú ọ wọlé, kó sì fún ọ ní ilẹ̀ wọn kí o lè jogún rẹ̀, bó ṣe rí lónìí.+

  • Jóṣúà 1:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Ilẹ̀ yín máa jẹ́ láti aginjù títí dé Lẹ́bánónì àti odò ńlá, ìyẹn odò Yúfírétì, gbogbo ilẹ̀ àwọn ọmọ Hétì,+ títí lọ dé Òkun Ńlá* ní ìwọ̀ oòrùn.*+

  • Jóṣúà 14:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Èyí ni ogún tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà ní ilẹ̀ Kénáánì, èyí tí àlùfáà Élíásárì àti Jóṣúà ọmọ Núnì àtàwọn olórí agbo ilé àwọn ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún wọn pé kí wọ́n jogún.+

  • Jeremáyà 3:19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 Mo sọ lọ́kàn mi pé, ‘Wo bí mo ṣe fi ọ́ sáàárín àwọn ọmọ tí mo sì fún ọ ní ilẹ̀ tó dára, ogún tó rẹwà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè!’*+ Mo tún sọ lọ́kàn mi pé, ẹ ó pè mí ní, ‘Bàbá mi!’ ẹ kò sì ní pa dà lẹ́yìn mi.

  • Ìṣe 17:26
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 26 Láti ara ọkùnrin kan ló ti dá+ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè láti máa gbé lórí gbogbo ilẹ̀ ayé,+ ó yan àkókò fún àwọn nǹkan, ó sì pa ààlà ibi tí àwọn èèyàn á máa gbé,+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́