-
Diutarónómì 3:12, 13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Nígbà yẹn, a gba ilẹ̀ yìí: láti Áróérì,+ èyí tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Àfonífojì Áánónì àti ìdajì agbègbè olókè Gílíádì, mo sì ti fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì+ ní àwọn ìlú rẹ̀. 13 Mo tún ti fún ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè+ ní ibi tó ṣẹ́ kù ní Gílíádì àti gbogbo Báṣánì tó jẹ́ ilẹ̀ ọba Ógù. Gbogbo agbègbè Ágóbù, tó jẹ́ ti Báṣánì, ni wọ́n mọ̀ sí ilẹ̀ àwọn Réfáímù.
-
-
Jóṣúà 13:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà tó kù, wá gba ogún wọn tí Mósè fún wọn lápá ìlà oòrùn Jọ́dánì, bí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe fún wọn:+
-