-
Léfítíkù 25:32-34Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
32 “‘Ní ti ilé àwọn ọmọ Léfì tó wà nínú àwọn ìlú wọn,+ àwọn ọmọ Léfì máa ní ẹ̀tọ́ láti ṣe àtúnrà àwọn ilé náà títí láé. 33 Tí àwọn ọmọ Léfì ò bá ra ohun ìní wọn pa dà, kí ilé tí wọ́n tà nínú ìlú wọn pa dà di tiwọn nígbà Júbílì,+ torí àwọn ilé tó wà nínú àwọn ìlú àwọn ọmọ Léfì jẹ́ ohun ìní wọn láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 34 Bákan náà, ẹ má ta ibi ìjẹko+ tó yí àwọn ìlú wọn ká, torí ohun ìní wọn ló jẹ́ títí láé.
-