11 “Àmọ́ tí ọkùnrin kan bá kórìíra ẹnì kejì rẹ̀,+ tó lúgọ dè é, tó ṣe é léṣe, tó sì kú, tí ọkùnrin náà sì sá lọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú yìí, 12 kí àwọn àgbààgbà ìlú rẹ̀ ránṣẹ́ pè é láti ibẹ̀, kí wọ́n sì fà á lé ẹni tó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́, ó gbọ́dọ̀ kú.+