-
Ẹ́kísódù 26:32Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
32 Kí o gbé e kọ́ sára òpó igi bọn-ọ̀n-ní mẹ́rin tí wọ́n fi wúrà bò. Kí o fi wúrà ṣe àwọn ìkọ́ wọn. Kí àwọn òpó náà wà lórí ìtẹ́lẹ̀ mẹ́rin tó ní ihò tí wọ́n fi fàdákà ṣe.
-
-
Ẹ́kísódù 26:37Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
37 Kí o fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe òpó márùn-ún fún aṣọ* náà, kí o sì fi wúrà bo àwọn òpó náà. Kí o fi wúrà ṣe àwọn ìkọ́ wọn, kí o sì fi bàbà ṣe ìtẹ́lẹ̀ márùn-ún tó ní ihò fún wọn.
-
-
Ẹ́kísódù 36:37, 38Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
37 Ó fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa tí wọ́n hun pọ̀ ṣe aṣọ* tí wọ́n máa ta sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà,+ 38 pẹ̀lú òpó rẹ̀ márùn-ún àti àwọn ìkọ́ wọn. Ó fi wúrà bo orí wọn àti àwọn ohun tó so wọ́n pọ̀,* àmọ́ bàbà ló fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ oníhò wọn márààrún.
-