26 “Kí o mú aṣọ mẹ́wàá tí wọ́n fi ń pa àgọ́, kí o sì fi ṣe àgọ́ ìjọsìn.+ Kí aṣọ náà jẹ́ aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa, pẹ̀lú fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò. Kí o kó iṣẹ́ sí wọn lára, kí iṣẹ́ náà+ jẹ́ àwòrán àwọn kérúbù.+