26 Lẹ́yìn tí àjàkálẹ̀ àrùn+ náà kásẹ̀ nílẹ̀, Jèhófà sọ fún Mósè àti Élíásárì ọmọ àlùfáà Áárónì pé: 2 “Ẹ ka gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti ẹni ogún (20) ọdún sókè, ní agbo ilé bàbá kọ̀ọ̀kan, kí ẹ ka gbogbo àwọn tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì.”+