12 “Nígbàkigbà tí o bá ka iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ kí kálukú mú ohun tí yóò fi ra ẹ̀mí* rẹ̀ pa dà wá fún Jèhófà nígbà ìkànìyàn náà. Èyí ò ní jẹ́ kí ìyọnu kankan ṣẹlẹ̀ sí wọn nígbà tí wọ́n bá forúkọ wọn sílẹ̀.
26 Ìlàjì ṣékélì tó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́* ni ìlàjì ṣékélì ẹnì kọ̀ọ̀kan, ìyẹn gbogbo ẹni tó wà lára àwọn tó forúkọ sílẹ̀ láti ẹni ogún (20) ọdún sókè,+ wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ àti àádọ́ta (603,550).+