Diutarónómì 28:10 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 10 Gbogbo èèyàn tó wà ní ayé á sì rí i pé orúkọ Jèhófà ni wọ́n fi ń pè ọ́,+ wọ́n á sì máa bẹ̀rù rẹ.+ Àìsáyà 43:7 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 7 Gbogbo ẹni tí wọ́n ń fi orúkọ mi pè,+Tí mo sì dá fún ògo mi,Tí mo ṣẹ̀dá, tí mo sì ṣe.’+ Àìsáyà 43:10 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 10 “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,”+ ni Jèhófà wí,“Àní ìránṣẹ́ mi tí mo ti yàn,+Kí ẹ lè mọ̀, kí ẹ sì ní ìgbàgbọ́ nínú mi,*Kó sì yé yín pé Ẹnì kan náà ni mí.+ Ṣáájú mi, kò sí Ọlọ́run tí a dá,Lẹ́yìn mi, kò sí ìkankan.+
10 “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,”+ ni Jèhófà wí,“Àní ìránṣẹ́ mi tí mo ti yàn,+Kí ẹ lè mọ̀, kí ẹ sì ní ìgbàgbọ́ nínú mi,*Kó sì yé yín pé Ẹnì kan náà ni mí.+ Ṣáájú mi, kò sí Ọlọ́run tí a dá,Lẹ́yìn mi, kò sí ìkankan.+