-
Jẹ́nẹ́sísì 48:17-19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Nígbà tí Jósẹ́fù rí i pé bàbá òun ò gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ kúrò lórí Éfúrémù, kò dùn mọ́ ọn nínú, ó sì gbìyànjú láti mú ọwọ́ bàbá rẹ̀ kúrò lórí Éfúrémù, kó sì gbé e sórí Mánásè. 18 Jósẹ́fù sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́ bàbá mi, àkọ́bí+ nìyí. Gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ lé e lórí.” 19 Àmọ́ bàbá rẹ̀ ò gbà, ó sì sọ pé: “Mo mọ̀, ọmọ mi, mo mọ̀. Òun náà á di èèyàn púpọ̀, yóò sì di ẹni ńlá. Àmọ́, àbúrò rẹ̀ máa jù ú lọ,+ àwọn ọmọ* rẹ̀ yóò sì pọ̀ bí àwọn orílẹ̀-èdè.”+
-