16 Àṣẹ Jèhófà ni pé, ‘Kí kálukú kó ìwọ̀n tó lè jẹ. Kí ẹ kó oúnjẹ tó kún òṣùwọ̀n ómérì kan*+ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan bí iye èèyàn* tó wà nínú àgọ́ kálukú yín bá ṣe pọ̀ tó.’”
23 Mósè sọ fún wọn pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyẹn. Gbogbo ọ̀la yóò jẹ́ ọjọ́ ìsinmi,* yóò jẹ́ sábáàtì mímọ́ fún Jèhófà.+ Ẹ yan ohun tí ẹ bá fẹ́ yan, ẹ se ohun tí ẹ bá fẹ́ sè;+ kí ẹ wá tọ́jú oúnjẹ tó bá ṣẹ́ kù di àárọ̀ ọ̀la.”