7 Ó ṣẹlẹ̀ pé mánà+ náà dà bí irúgbìn kọriáńdà,+ ó sì rí bíi gọ́ọ̀mù bídẹ́líọ́mù. 8 Àwọn èèyàn náà máa ń lọ káàkiri láti kó o, wọ́n á sì fi ọlọ lọ̀ ọ́ tàbí kí wọ́n gún un nínú odó. Wọ́n á wá sè é nínú ìkòkò tàbí kí wọ́n fi ṣe búrẹ́dì ribiti,+ bí àkàrà dídùn tí wọ́n fi òróró sí ló rí lẹ́nu.