-
Ẹ́kísódù 4:14-16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Jèhófà wá bínú sí Mósè, ó sì sọ pé: “Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ+ tó jẹ́ ọmọ Léfì ńkọ́? Mo mọ̀ pé ó lè sọ̀rọ̀ dáadáa. Ó sì ti ń bọ̀ wá bá ọ níbí báyìí. Tó bá rí ọ, inú rẹ̀ yóò dùn.+ 15 Kí o bá a sọ̀rọ̀, kí o sì fi àwọn ọ̀rọ̀ náà sí ẹnu rẹ̀,+ màá wà pẹ̀lú ẹ̀yin méjèèjì bí o ṣe ń sọ̀rọ̀,+ màá sì kọ́ yín ní ohun tí ẹ máa ṣe. 16 Yóò bá ọ bá àwọn èèyàn náà sọ̀rọ̀, òun ló máa jẹ́ agbẹnusọ fún ọ, ìwọ yóò sì dà bí Ọlọ́run fún un.*+
-
-
Ẹ́kísódù 4:30Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
30 Áárónì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Mósè fún wọn, ó sì ṣe àwọn iṣẹ́ àmì náà+ níṣojú àwọn èèyàn náà.
-
-
Ẹ́kísódù 15:20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Míríámù wòlíì obìnrin, ẹ̀gbọ́n Áárónì wá mú ìlù tanboríìnì, gbogbo obìnrin sì ń jó tẹ̀ lé e pẹ̀lú ìlù tanboríìnì.
-