11 “‘Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù kọ̀ọ̀kan,* kí ẹ mú akọ ọmọ màlúù méjì, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje tí ara wọn dá ṣáṣá tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan+ wá láti fi rú ẹbọ sísun sí Jèhófà,
14 Kí ọrẹ ohun mímu wọn jẹ́ wáìnì ìdajì òṣùwọ̀n hínì fún akọ màlúù+ kan àti ìdá mẹ́ta òṣùwọ̀n hínì fún àgbò+ náà àti ìlàrin òṣùwọ̀n hínì fún akọ ọ̀dọ́ àgùntàn+ kan. Èyí ni ẹbọ sísun oṣooṣù fún oṣù kọ̀ọ̀kan, jálẹ̀ ọdún.