-
2 Kíróníkà 2:4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Ní báyìí, mo fẹ́ kọ́ ilé fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run mi, láti yà á sí mímọ́ fún un, láti máa sun tùràrí onílọ́fínńdà+ níwájú rẹ̀ àti láti máa kó búrẹ́dì onípele* síbẹ̀ ní gbogbo ìgbà+ àti àwọn ẹbọ sísun ní àárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́,+ ní àwọn Sábáàtì,+ ní àwọn òṣùpá tuntun+ àti ní àwọn àsìkò àjọyọ̀+ Jèhófà Ọlọ́run wa. Ohun tí Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ máa ṣe nìyẹn títí láé.
-
-
Nehemáyà 10:32, 33Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
32 Bákan náà, a gbé àṣẹ kan kalẹ̀ fún ara wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan pé, a ó máa mú ìdá mẹ́ta ṣékélì* wá lọ́dọọdún fún iṣẹ́ ìsìn ilé* Ọlọ́run wa,+ 33 fún búrẹ́dì onípele,*+ ọrẹ ọkà ìgbà gbogbo,+ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo ti Sábáàtì+ pẹ̀lú ti òṣùpá tuntun+ àti fún àwọn àsè tí a yàn,+ àwọn ohun mímọ́ àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ láti ṣe ètùtù fún Ísírẹ́lì àti fún gbogbo iṣẹ́ ilé Ọlọ́run wa.
-