-
Léfítíkù 24:5-7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 “Kí o mú ìyẹ̀fun tó kúnná, kí o fi ṣe búrẹ́dì méjìlá (12) tó rí bí òrùka. Ìyẹ̀fun tó jẹ́ ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà* ni kí o fi ṣe búrẹ́dì kọ̀ọ̀kan. 6 Kí o tò wọ́n ní ìpele méjì, mẹ́fà ní ìpele kan,+ lórí tábìlì tí wọ́n fi ògidì wúrà ṣe, èyí tó wà níwájú Jèhófà.+ 7 Kí o fi ògidì oje igi tùràrí sórí ìpele kọ̀ọ̀kan, yóò sì jẹ́ búrẹ́dì ọrẹ ìṣàpẹẹrẹ*+ tó jẹ́ ọrẹ àfinásun sí Jèhófà.
-