9 Ó sọ pé: “Jèhófà, tí mo bá ti rí ojúure rẹ, jọ̀ọ́ Jèhófà, máa bá wa lọ kí o sì wà láàárín wa,+ bó tiẹ̀ jẹ́ pé alágídí* ni wá,+ kí o dárí àṣìṣe àti ẹ̀ṣẹ̀ wa jì,+ kí o sì mú wa bí ohun ìní rẹ.”
19 Èmi yóò fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ní àwọn ọmọ Léfì bí àwọn tí a fi fúnni láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí wọ́n lè máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé+ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí wọ́n sì máa ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ kí ìyọnu má bàa dé bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì torí wọ́n sún mọ́ ibi mímọ́.”