51 Nígbàkigbà tí ẹ bá fẹ́ kó àgọ́ ìjọsìn náà kúrò,+ àwọn ọmọ Léfì ni kó tú u palẹ̀; tí ẹ bá sì fẹ́ to àgọ́ ìjọsìn náà pa dà, àwọn ọmọ Léfì ni kó tò ó; tí ẹnikẹ́ni tí kò lẹ́tọ̀ọ́* bá sún mọ́ ọn, ṣe ni kí ẹ pa á.+
4 Kí wọ́n dara pọ̀ mọ́ ọ, kí wọ́n sì máa ṣe ojúṣe wọn tó jẹ mọ́ àgọ́ ìpàdé àti gbogbo iṣẹ́ àgọ́ náà, ẹnikẹ́ni tí kò lẹ́tọ̀ọ́* sí i kò sì gbọ́dọ̀ sún mọ́ yín.+
7 Ojúṣe ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ni láti máa ṣe iṣẹ́ àlùfáà tó jẹ mọ́ pẹpẹ àtàwọn ohun tó wà lẹ́yìn aṣọ ìdábùú,+ ẹ̀yin ni kí ẹ máa ṣe iṣẹ́ yìí.+ Mo ti fi iṣẹ́ àlùfáà ṣe ẹ̀bùn fún yín, ṣe ni kí ẹ pa+ ẹnikẹ́ni tí kò lẹ́tọ̀ọ́* sí i tó bá sún mọ́ tòsí.”