ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 23:19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 “Kí o mú èyí tó dáa jù nínú àwọn èso tó kọ́kọ́ pọ́n ní ilẹ̀ rẹ wá sí ilé Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+

      “O ò gbọ́dọ̀ se ọmọ ewúrẹ́ nínú wàrà ìyá rẹ̀.+

  • Léfítíkù 27:28
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 28 “‘Àmọ́ tí ẹnì kan bá ti ya ohunkóhun sọ́tọ̀ pátápátá* fún Jèhófà látinú àwọn ohun tó ní, ì báà jẹ́ èèyàn tàbí ẹran tàbí ilẹ̀ tó jẹ́ tirẹ̀, kò gbọ́dọ̀ tà á tàbí kó rà á pa dà. Gbogbo ohun tí èèyàn bá ti yà sọ́tọ̀ jẹ́ ohun mímọ́ jù lọ fún Jèhófà.+

  • Léfítíkù 27:30
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 30 “‘Gbogbo ìdá mẹ́wàá+ ilẹ̀ náà jẹ́ ti Jèhófà, ì báà jẹ́ látinú irè oko ilẹ̀ náà tàbí èso igi. Ohun mímọ́ fún Jèhófà ni.

  • Nọ́ńbà 18:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Ìwọ náà lo tún ni èyí: àwọn ẹ̀bùn tí wọ́n mú+ wá pẹ̀lú gbogbo ọrẹ fífì+ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá mú wá. Mo ti fún ìwọ àtàwọn ọmọkùnrin rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ pẹ̀lú rẹ, kó jẹ́ ìpín+ yín títí lọ. Gbogbo ẹni tó mọ́ nínú ilé rẹ ló lè jẹ ẹ́.+

  • Nọ́ńbà 18:26
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 26 “Sọ fún àwọn ọmọ Léfì pé, ‘Ẹ ó máa gba ìdá mẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, èyí tí mo fún yín láti ọwọ́ wọn kó lè jẹ́ ogún+ yín, kí ẹ sì fi ìdá mẹ́wàá lára ìdá mẹ́wàá náà ṣe ọrẹ fún Jèhófà.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́