-
Nọ́ńbà 13:26Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 Wọ́n sì pa dà sọ́dọ̀ Mósè àti Áárónì àti gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní aginjù Páránì, ní Kádéṣì.+ Wọ́n jábọ̀ fún gbogbo àpéjọ náà, wọ́n sì fi àwọn èso ilẹ̀ náà hàn wọ́n.
-
-
Nọ́ńbà 20:22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 Gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá kúrò ní Kádéṣì, wọ́n sì wá sí Òkè Hóórì.+
-
-
Nọ́ńbà 33:36Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
36 Lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Esioni-gébérì, wọ́n pàgọ́ sí aginjù Síínì,+ ìyẹn Kádéṣì.
-
-
Diutarónómì 2:14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Ọdún méjìdínlógójì (38) la fi rìn láti Kadeṣi-bánéà títí a fi sọdá Àfonífojì Séréédì, títí gbogbo ìran àwọn ọkùnrin ogun fi pa run láàárín àpéjọ, bí Jèhófà ṣe búra fún wọn gẹ́lẹ́.+
-