10 Ó fèsì pé: “Ìtara Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun+ gbà mí lọ́kàn ni; nítorí àwọn èèyàn Ísírẹ́lì ti pa májẹ̀mú rẹ tì,+ wọ́n ti ya àwọn pẹpẹ rẹ lulẹ̀, wọ́n ti fi idà pa àwọn wòlíì rẹ,+ èmi nìkan ló sì ṣẹ́ kù. Ní báyìí, bí wọ́n ṣe máa gba ẹ̀mí mi ni wọ́n ń wá.”+