38 Kí ẹ fi ìkóná àwọn èèyàn tó ṣẹ̀ tí wọ́n sì fi ẹ̀mí ara wọn dí i ṣe àwọn irin pẹlẹbẹ tí ẹ máa fi bo pẹpẹ,+ torí iwájú Jèhófà ni wọ́n mú un wá, ó sì ti di mímọ́. Kó máa jẹ́ àmì fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”+
10 Bákan náà, kí ẹ má ṣe máa kùn, bí àwọn kan nínú wọn ṣe kùn,+ tí apanirun sì pa wọ́n.+11 Àwọn nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ sí wọn kí ó lè jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa,+ wọ́n sì wà lákọsílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìkìlọ̀ fún àwa tí òpin àwọn ètò àwọn nǹkan dé bá.